Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Tírà Tí A Sọ̀ Kalẹ̀

Mùsùlùmí ní láti gbàgbọ́ nínú gbogbo àwọn Tírà tí Allāh sọ̀ kalẹ̀ fún àwọn Ànábì Rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àkájọ ìwé (Ṣuḥuf) ti Ànábì Ibrāhīm àti Mūsā, Zabūr ti Ànábì Dāwūd, àti Ínjīl ti Ànábì Īsā (kí ọlà Allāh máa bá wọn). Ìgbàgbọ́ yìí jẹ́ apá kan pàtàkì tí kò ṣe é yọ kúrò nínú ìpìlẹ̀ ẹ̀sìn rẹ̀. Ó jẹ́rìí sí i pé Allāh ni Orísun ìtọ́sọ́nà àti òtítọ́, tí Ó fi bá aráyé sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́-ìránṣẹ́ ọ̀run Rẹ̀ tó tẹ̀ lé ara wọn. Èyí á sì jẹ́ kí ọkàn onígbàgbọ́ kún fún ọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn Ànábì tó mú àwọn iṣẹ́-ìránṣẹ́ wọ̀nyí dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn.

Al-Qur'ān Alápọ̀n-ọlá ni olùdarí àti adájọ́ lórí àwọn Tírà ọ̀run tó ti ṣáájú rẹ̀. Òun ni òṣùwọ̀n tí a fi ń díwọ̀n àwọn àkọsílẹ̀ tó wà lọ́wọ́ wa lónìí. Gbogbo ohun tó bá bá Al-Qur'ān mu nínú àwọn ìròyìn inú Tírà wọ̀nyẹn ni a gbàgbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́ tó sì wà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, èyí tó bá ta ko tàbí lòdì sí i, a ní ìdánilójú pé àyípadà àti àtúnṣe ti bá a láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, kò sì dúró fún ọ̀rọ̀ Allāh gẹ́lẹ́ bí ó ṣe sọ̀ kalẹ̀ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Al-Qur'ān Alápọ̀n-ọlá wá gẹ́gẹ́ bí olùjẹ́rìí sí òtítọ́ àwọn iṣẹ́-ìránṣẹ́ tó ṣáájú rẹ̀, ó sì tún ṣe àtúnṣe sí àwọn ibi tí àyípadà ti wọ̀ wọ́n. Ní àfikún, ó mú ìròyìn ayọ̀ nípa wíwá Ànábì Muhammad ﷺ wá, èyí tó ti wà nínú Taorāti àti Ínjīl. Ìjẹ́rìí yìí fi hàn pé Orísun kan ṣoṣo ni gbogbo àwọn iṣẹ́-ìránṣẹ́ náà ti wá, ìyẹn ọ̀dọ̀ Allāh. Ó sì sọ Al-Qur'ān di orísun ìtọ́kàsí ìkẹyìn àti olùṣọ́ tó dájú, èyí tó pa òtítọ́ ohun tí Allāh fẹ́ nínú àwọn Tírà àtijọ́ wọ̀nyẹn mọ́ fún gbogbo aráyé.

Kókó ìgbàgbọ́ nínú àwọn Tírà wọ̀nyí ni pé kí a fara mọ́ ọn pé ìtọ́sọ́nà àti ìmọ́lẹ̀ ni wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbàgbọ́ pé àyípadà ti wọ àwọn Tírà àtijọ́, a kò gbọ́dọ̀ fojú fò wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti di àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ pàtàkì inú wọn tí Al-Qur'ān sọ fún wa mú, èyí tí Allāh ti sọ di àìkú nínú Tírà Rẹ̀ (Al-Qur'ān). Nípa báyìí, Mùsùlùmí yóò wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀léra àwọn Ànábì alábùkún, yóò máa bu ọlá fún gbogbo iṣẹ́-ìránṣẹ́ Allāh, yóò sì di Al-Qur'ān mú gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìgbésí ayé rẹ̀.

يؤمن المسلم بجميع الكتب التي أنزلها الله على أنبيائه، كصحف إبراهيم وموسى، وزبور داود، وإنجيل عيسى عليه السلام. هذا الإيمان جزء لا يتجزأ من عقيدته، حيث يقر بأن الله هو مصدر الهداية والحق الذي خاطب به البشرية عبر رسالاته السماوية المتتالية، مما يغرس في نفس المؤمن احترام جميع الأنبياء الذين بلغوا هذه الرسالات للناس.

يعد القرآن الكريم المهيمن والحاكم على ما سبقه من الكتب السماوية؛ فهو الميزان الذي نزن به ما بين أيدينا اليوم من نصوص. فكل ما وافق القرآن من أخبار تلك الكتب نؤمن بصحته وبقائه، أما ما خالفه أو تناقض معه، فنوقن بأنه تعرض للتحريف والتبديل على مر العصور، ولا يمثل كلام الله الأصلي كما نزل.

لقد جاء القرآن الكريم مصدقاً لما قبله من رسالات مع تصحيح ما لحق بها من تحريف، بل وجاء بالبشارة بالنبي محمد ﷺ في التوراة والإنجيل. إن هذا التصديق يبين وحدة المصدر الإلهي، ويجعل من القرآن المرجع النهائي والأمين الذي يحفظ للبشرية حقيقة ما أراده الله في تلك الرسالات المنزلة سابقاً.

إن جوهر الإيمان بهذه الكتب يكمن في التسليم بأنها هدى ونور. ومع إيماننا بوقوع التحريف في الكتب السابقة، لا نتجاهلها، بل نتمسك بما أخبرنا القرآن عن جوهر أحكامها وقيمها التي خلدها الله في كتابه. وبذلك، يظل المسلم موصولاً بسلسلة النبوات المباركة، محترماً لرسالات الله جميعاً، ومتمسكاً بالقرآن كمنهج حياة.